| |
El período embrionario (Las primeras 8 semanas)
Desarrollo embrionario: Las primeras 4 semanas
Capítulo 3 Fecundación
|
| |
| Bi a ba nsọrọ nipa awọn ohun alaaye,
"idagbasoke enia bẹrẹ lati igbati idapọ
ba w’aye laarin ẹyin ọkunrin ati obirin,"
nigbati ọkunrin ati obirin
ba da mẹtaleloogun ninu awọn
eroja ti o wa ninu ẹya-ara wọn pọ,
nipasẹ idapọ ẹya-ara ti o wa fun ọmọ bibi.
Ẹya-ara ti o wa fun ọmọ bibi ninu
ara obirin ni a npe ni "ẹyin"
Sugbọn ohun ti o yẹ ki a pee ni oosaiti.
Bakanna, ẹya-ara ti o wa fun
ọmọ bibi lara ọkunrin
ni a npe ni "sipaamu,"
Sugbọn ọrọ ti o dara julọ
fun eyi ni sipamatosoonu.
Lẹhin ti ẹyin ba ti jade tan
kuro ninu apo ẹyin obirin
nipasẹ ọna ti a npe ni ofulesan,
ẹyin naa ati sipamatosoonu yio dapọ
ninu ọkan lara okun ile ọmọ,
eyiti a npe ni okun Falopiani.
Awọn okun ile ọmọ yi
ni o so ile ẹyin obirin
pọ mọ ile ọmọ tabi wohunbu.
Abajade idapọ yi ni nfa oyun,
eyiti a npe ni saigọọti,
itumọ eyiti nS̩e "isopọ
tabi idapọ sọkan."
|
Capítulo 4 ADN, división celular y factor temprano de embarazo
|
| |
| Awọn eroja mẹrindinlaadọta
ti o wa ninu saigọọti
duro fun ekini ninu awọn alailẹgbẹ
eto igbesi aye ọmọ enia titun.
Eto pataki yi wa ninu
awọn ohun kan ninu agọ ara
ti a npe ni DNA.
Ninu wọn ni asẹ fun idagbasoke
gbogbo ara enia wa.
Awọn ohun ti a npe ni DNA
yi farajọ akaba ti o lọ pọ,
ti a npe ni dọbulu hẹlikisi.
Lara akasọ ara akaba naa ni
awọn ohun kan,
ti a npe ni guanini,
sitosini, adinini, ati taamini wa.
|
| Guanini yi le darapọ mọ sitosini nikan,
adinini si le darapọ mọ taamini.
Ọkọọkan ninu awọn ẹyin keekeke
ti a fi da enia ni o ni ọkẹ aimoye
awọn ohun ti a darukọ
loke wọnyi ninu.
DNA inu ọkan ninu awọn ẹyin keekeke
ti a fi da enia yi ni oriS̩iriS̩i alaye ninu,
ti o jẹ wipe, bi a ba fẹ kọ wọn
silẹ ni ọrọ,
lẹta ekini ninu ọkọọkan
awọn ohun ti a darukọ wọnyi
yio gba oju ewe iwe
ti o to miliọnu kan ati aabọ!
Bi a ba gbe wọn si ẹgbẹ ara wọn,
DNA inu okansoso ninu awọn ẹyin keekeke
wọnyi yio gun to iwọn ẹsẹ mẹta ati diẹ
tabi mita kan.
|
| Bi a ba le tu gbogbo DNA yi palẹ
ninu ọkẹ aimọye ẹyin keekeke
ti o wa ni ara agbalagba enia,
yio gun to iwọn mẹtalelọgọta
biliọnu maili.
Gigun rẹ yi to ki a rin irin ajo lati aye
lọ si ibiti oorun wa, ati ki a pada
ni ọọdun igba, o le ni ogoji.
|
| O fẹrẹ to wakati mẹrinleloogun si ọgbọn
wakati lẹhin idapọ ẹyin ọkunrin ati obirin,
ki saigọọti to pari
pinpin si meji rẹ akọkọ.
Nipasẹ ọna ti a npe ni maitosisi,
ẹyin kan yio pin si meji,meji yio pin
si mẹrin, ati bẹẹbẹẹ lọ.
|
| Laarin wakati mẹrinleloogun si wakati
mejidinlaadọta lẹhin ti idapọ ti waye,
a le sọ daju pe oyun ti wa nipo, nipasẹ
ọkan ninu awọn ohun kan ti a npe ni homonu,
eyiti orukọ rẹ njẹ "olufihan
oyun inu titun”, ti o wa ninu ẹjẹ iya ọmọ.
|
Capítulo 5 Etapas iniciales (mórula y blastocito) y células madre
|
| |
| Laarin ọjọ mẹta si mẹrin lẹhin
idapọ ẹyin ọkunrin ati obirin,
ẹyin naa yio maa pin si ọna
pupọ, wọn a ri rogodo,
a si npe oyun inu naa nisisiyi ni morula.
Laarin ọjọ mẹrin si marun, iho kan
yio waye laarin awọn ẹyin rogodo wọnyi,
a si npe oyun inu naa
nisisiyi ni bilasitosisiti.
Awọn ẹyin keekeke ti o wa ninu
bilasitosisiti yi
ni a npe ni akojọpọ ẹyin ti inu,
eyiti yio ko ara wọn jọ pọ lati
di ori, ara, ati awọn ẹya ara miran
ti o S̩e pataki fun idagbasoke ọmọ enia.
Awọn ẹyin ti a fi ns’ẹda enia, eyiti
o wa ninu akojọpọ ẹyin ti inu yi
ni a npe ni ẹyin oyun ti o l’ẹka,
nitori wipe wọn lagbara
lati di ọkan ninu iru awọn orisirisi
ẹyin keekeke ti o le ni igba,
eyiti o wa ni ara ọmọ enia.
|
Capítulo 6 1 a 1½ semanas: implantación y gonadotropina coriónica humana (GCH)
|
| Nigbati o ba kuro ninu okun ile ọmọ,
oyun inu titun yi yio gbin ara rẹ
sinu ẹran ara ti o wa ni ayika
ile ọmọ iya rẹ.
Ilana yi, ti a npe ni gbigbin nkan,
ma nbẹrẹ ni ọjọ kẹfa,
yio si pari ni ọjọ kẹwa si ekejila
lẹhin idapọ ẹyin ọkunrin ati obirin.
Ẹyin keekeke ara oyun inu ti ndagba
yi a bẹrẹ sii mu orisi homonu kan jade,
eyiti a npe ni hCG,
eyiti o si ma nfarahan nigbati
a ba S̩e ayewo lati mọ boya oyun ti duro.
HCG ma ntọ homonu ara iya
lati da nkan osu duro,
ki oyun baa le dagbasoke siwaju sii.
|
Capítulo 7 La placenta y el cordón umbilical
|
| Lẹhin ti oyun ba ti gbin ara
rẹ si ile ọmọ iya rẹ tan,
awọn ẹyin keekeke ti o wa l’ẹba
bilasitosisiti yi
yio di lara ẹya ohun
ti a npe ni ibi-ọmọ,
eyiti o so
ẹya ara ti ngbe ẹjẹ yika ara iya
pọ mọ ti ọmọ inu oyun.
Ibi-ọmọ yi a ma gbe atẹgun, ounjẹ,
homonu ati oogun lati ara iya
lọ si ara ọmọ inu oyun ti ndagba naa;
o si tun ma nmu idọti ara kuro;
kii si jẹki ẹjẹ ara iya dapọ mọ ẹjẹ
ara ọmọ inu oyun.
Ibi-ọmọ ma nmu awọn homonu jade,
o si ma nmu ki iwọn otutu
tabi ooru ara ọmọ inu oyun
o pọ diẹ ju ti ara iya rẹ lọ.
Ohun ti a fi so ibi-ọmọ pọ mọ oyun inu
ni okun ibi-ọmọ.
A le fi ọna ti ibi-ọmọ ngba
se atilẹhin fun ẹmi ọmọ inu oyun
we iyara ti a ti nse itọju awọn enia ti
o wa labẹ ewu, ni ile iwosan igbalode.
|
Capítulo 8 Nutrición y protección
|
| |
| Lẹhin ọsẹ kan,
ẹyin keekeke ti o wa lara
akojọpọ ẹyin inu
yio di awọ fẹlẹfẹlẹ meji ti a npe ni
aipobilasiti
ati ẹpibilasiti.
Aipobilasiti yi
ni yio di ohun ti a npe ni
apo ẹyin,
eyiti o jẹ ọkan lara awọn ẹya ara,
nipasẹ eyiti
iya yio maa gba fun
oyun inu rẹ l’ounjẹ.
Ẹyin keekeke
lati ara ẹpibilasiti yio di
awọ fẹlẹfẹlẹ kan ti a npe ni aminiọnu,
ninu eyiti ọmọ inu oyun ti a S̩ẹS̩ẹ ni,
ati ọmọ inu oyun ti o ti le ni ọsẹ mẹjọ
yio ti maa dagbasoke
titi di akoko ibimọ.
|
Capítulo 9 2 a 4 semanas: capas germinales y formación de órganos
|
| |
| Lẹhin ọsẹ meji ati aabọ,
ẹpibilasiti yio ti di
oriS̩i ẹya ara mẹta,
tabi awọ fẹlẹfẹlẹ,
ti a npe ni ẹkitodaamu,
ẹndodaamu,
ati mẹsodaamu.
Ekitodaamu yio di
awọn oriS̩iriS̩i ẹya ara
bii ọpọlọ,
ọpa-ẹhin,
iS̩an-ara,
awọ-ara,
eekanna,
ati irun.
Ẹndodaamu yio di awọ ti a fi tẹ inu
ẹya ara ti atẹgun ngba lara enia
ati ti inu ẹya ara ti ounjẹ ngba,
yio si tun di lara
oriS̩iriS̩i awọn ẹya ara miran
bii ẹdọ
ati ẹya ara ti oronro ngbe inu rẹ.
Mẹsodaamu yio di ọkan,
kidinrin,
egungun,
kerekere,
iS̩an,
ẹjẹ,
ati awọn ẹya miran.
|
| Lẹhin ọsẹ mẹta
ọpọlọ yio pin si ọna mẹta ọtọọtọ
ti a npe ni ọpọlọ iwaju,
ọpọlọ aarin,
ati ọpọlọ ẹhin.
Idagbasoke awọn ẹya ara
ti ngbe ẹjẹ ati ounjẹ kaakiri ara
ti bẹrẹ pẹlu.
|
| Bi ẹjẹ akọkọ
ba ti de inu apo ẹyin,
iho ara ti ẹjẹ ngba yio farahan
kaakiri lara ọmọ inu oyun naa,
bẹẹ si ni ọkan, eyiti o ri rogodo,
yio farahan bakanna.
O fẹrẹ jẹ lẹsẹkanna
ni ọkan ti ndagbasoke ni kiakia yi
yio sẹpo sori ara rẹ,
bẹẹ si ni apo ọtọọtọ
yio maa waye laarin ọkan naa.
Ọkan naa yio bẹrẹ sii mi
lati ọsẹ kẹta ati ọjọ kan
lẹhin idapọ ẹyin ọkọ ati aya.
Ẹya ara ti ngbe ẹjẹ kiri gbogbo ara
jẹ ẹya ara akọkọ,
tabi akojọpọ awọn ẹya ara
ti o jọ ara wọn
lati bẹrẹ sii S̩iS̩ẹ.
|
Capítulo 10 3 a 4 semanas: el plegamiento del embrión
|
| |
| Larin ọsẹ mẹta si mẹrin,
awọn eto ẹya ara yio yanju,
gẹgẹbi ọpọlọ,
ọpa-ẹhin,
ati ọkan ọmọ inu oyun naa,
eyiti a le fi irọrun damọ
lati ẹgbẹ apo ẹyin.
Idagbasoke yi ma nmu ki
oyun inu ti o ti S̩e pẹrẹsẹ tẹlẹ ri
ki o sẹpo.
Ilana yi a maa so
lara apo ẹyin
pọ mọ awọ ti a fi tẹ inu
ẹya ara ti ngbe ounjẹ kaakiri ara enia,
wọn yio si di aya
ati inu ikun
ọmọ inu oyun ti ndagba naa.
|