Skip Navigation

National Geographic Society Este programa se distribuye en los Estados Unidos y Canadá por National Geographic y EHD. [obtenga más información]

DVD ilustrado plurilingüe

La biología del desarrollo prenatal


6 meses hasta el nacimiento


ẸKỌ NIPA IDAGBASOKE ỌMỌ NINU OYUN KI A TO BI I S’AYE

.Yoruba


 

Descargar versión en formato PDF  ¿Qué es PDF?
 

Capítulo 43   5 a 6 meses (20 a 24 semanas): responde al sonido; cabello y piel; edad de viabilidad

Ni ọsẹ kẹrinleloogun, ipenpeju yio S̩i soke, oyun inu naa yio si S̩ẹju ni iyalẹnu. Iru ifesi bayi si ariwo ti a pa lojiji ti ma nwaye ni kiakia ju bayi lọ lara ọmọ inu oyun ti o jẹ obirin.

Awọn oluwadi fi ye wa wipe ariwo ti o pọ ju le S̩e jamba fun ilera ọmọ inu oyun. Awọn ijamba tii ma ntete waiye ni ki ọkan maa mi titi laini idaduro, ki ọmọ inu oyun maa gbe itọ mi ju bi o ti yẹ lọ, ati awọn iwa ojiji miran. Awọn jamba ti maa waye lọjọ pipẹ lẹhin eyi ni ailegbọran daada.

Iwọn bi ọmọ inu oyun se nmi le lọ soke to fifa atẹgun simu lẹẹmẹrinlelogoji laarin iS̩ẹju kan.

Ni asiko ti o jẹ ipele kẹta ninu igba ti obirin fi nloyun, idagbasoke ọpọlọ ma nlo to idaji ninu gbogbo okun inu ti ọmọ inu oyun nlo. Ọpọlọ yio tobi sii ni iwọn ti o to ilọpo mẹrin si marun.

Ni ọsẹ kẹrindinlọgbọn, oju yio yọ omije.

Ẹyin oju ma nfesi si imọlẹ lati bi ọsẹ kẹtadinlọgọn. Ifesi yi ma nse ilana bi imọlẹ ti ntan sinu ẹyin oju, ni gbogbo ọjọ ti ọmọ naa yio gbe laye.

Ohun gbogbo ti o wulo fun gbigb’oorun nkan ti bẹrẹ sii S̩iS̩ẹ. Ẹkọ lori awọn ọmọ ti osu wọn ko pe S̩e akiyesi agbara ati gbọ oorun lati bi ọsẹ kẹrindinlọgbọn lẹhin idapọ ẹyin.

Bi a ba fi ohun ti o ladun sinu omira apo ile-ọmọ, ọmọ naa yio ma gbe itọ mi ju bi o ti yẹ lọ. Sugbọn ọmọ inu oyun kii gbe itọ mi to bi o ti yẹ bi a ba fi ohun ti o koro sinu omira. Ọmọ naa yio fun oju rẹ pọ lẹhin naa.

Nipasẹ oriS̩iriS̩i awọn igbesẹ bi ti enia ti nrin, ọmọ inu oyun naa ma ntakiti ọbọ.

Ara ọmọ inu oyun naa ki yio wunjọ bii ti atẹhinwa bi ọra S̩e nkun abẹ awọ-ara rẹ. Ọra nS̩e iS̩ẹ pataki ni mimu iwọn otutu tabi ooru ara enia duro, ati ni pipese okun-inu lẹhin ibimọ.

Capítulo 44   7 a 8 meses (28 a 32 semanas): discriminación de sonidos, estados de comportamiento

Ni ọsẹ kejidinlọgbọn, ọmọ inu oyun le mọ iyatọ laarin bi nkan S̩e ndun si ni leti.

Ni ọgbọn ọsẹ, fifa atẹgun s’imu wọ pọ, o si ma nwaye ni iwọn ọgbọn si ogoji ninu ọgọrun igba, lara ọmọ inu oyun.

Ni oS̩u mẹrin ti o kẹhin ninu oyun, ọmọ inu oyun ma nhu awọn iwa kan letoleto, laarin eyiti o ma nni akoko isinmi. Awọn iwa wọnyi nfihan bi isẹ ti ọpọlọ ati awọn ka rẹ nS̩e ti lagbara to.

Capítulo 45   Las extremidades y la piel

Nigbati o ba to ọsẹ mejilelọgbọn, awọn iho, tabi apo atẹgun, yio bẹrẹ sii waye ninu ẹdọforo. Wọn yio maa dagba sii titi di igba ti ọmọ naa yio pe ọmọ ọdun mẹjọ.

Ni ọsẹ karundinlogoji, ọmọ inu oyun le di nkan mu giri.

Ohun ti o wa ni ayika ibiti oyun inu ti dagba ma ntọka si awọn ohun ti yio fẹran lati maa jẹ lẹhin ti a ba bii. Fun apẹẹrẹ, ọmọ inu oyun ti iya rẹ jẹ ohun ti a npe ni aniisi, eyiti o fun ounjẹ kan ti a npe ni likorisi ni adun rẹ, fẹran lati maa jẹ aniisi naa lẹhin ti a bii tan. Ọmọ ikoko ti iya rẹ ko ni ohun kan se pẹlu aniisi ko fẹran ounjẹ naa rara.

Capítulo 46   9 meses hasta el nacimiento (36 semanas hasta el nacimiento)

Ọmọ inu oyun yio mu ki irọbi bẹrẹ nigbati ohun kan ti a npe ni ẹsitirogini ba njade lara rẹ, ti o si bẹrẹ ayipada rẹ lati ọmọ inu oyun si ọmọ ikoko.

Rirọbi ma nwaye pẹlu sisunki ile-ọmọ, eyiti yio fa bibi ọmọ.

Lati akoko idapọ ẹyin titi di igba ibimọ ati siwaju sii, idagbasoke ọmọ enia ta yọ, o wa titi aye, o si jẹ ohun ti o diju lọpọlọpọ. Imọ ẹkọ titun nipa ilana ti o fanimọra yi nfi anfaani ti o wa ninu idagbasoke oyun lori ilera ọmọ enia ni gbogbo igbesiaye rẹ han.

Bi imọ wa nipa idagbasoke ọmọ ninu oyun ti ntẹsiwaju, bẹẹni anfaani ti a ni lati jẹki ilera ọmọ enia tubọ fẹsẹmulẹ ngbooro sii- ki a to bimọ, ati bi a ba bii tan.
6 meses hasta el nacimiento